Jeremiah 23:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rí nǹkankan tí ó burú lọ́wọ́ àwọn wolii Samaria: Ẹ̀mí oriṣa Baali ni wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọ́n sì ń ṣi àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi, lọ́nà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si ti ri were ninu awọn woli Samaria, nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ Baali, nwọn si mu Israeli enia mi ṣina.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Láàrin àwọn wòlíì Saáríà, Èmi rí ohun tí ń lé ni sá: Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Báálì wọ́n sì mú Ísírẹ́lì ènìyàn mi sìnà.