Jeremiah 23:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rí nǹkankan tí ó bani lẹ́rù lọ́wọ́ àwọn wolii Jerusalẹmu: Wọ́n ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, wọ́n ń hùwà èké; wọ́n ń ran àwọn ẹni ibi lọ́wọ́, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni yipada kúrò ninu iṣẹ́ ibi rẹ̀. Gbogbo wọn ti di ará Sodomu lójú mi, àwọn ará Jerusalẹmu sì dàbí àwọn ará Gomora.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti láàrin àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù, èmi ti rí ohun búburú: Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké. Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára, tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀. Gbogbo wọn dàbí Sódómù níwájú mi, àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gòmórà.”