Jeremiah 23:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa àwọn wolii pé: N óo fún wọn ní ewé igi kíkorò jẹ, n óo fún wọn ní omi májèlé mu. Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ àwọn wolii Jerusalẹmu ni ìwà burúkú ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí ní ti àwọn wòlíì: “Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò, wọn yóò mu omi májèlé nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mù ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”