Jeremiah 23:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń sọ lemọ́lemọ́ fún àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí pé, yóo dára fún wọn. Wọ́n ń wí fún gbogbo àwọn tí wọn ń tẹ̀lé àìgbọràn ọkàn wọn pé ibi kò ní bá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, ‘OLÚWA ti wí pé: Ẹ ó ní àlàáfíà,’ Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé, ‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’