Jeremiah 23:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn tí ó fi ṣọ́ àwọn eniyan rẹ̀, láti máa bojútó wọn pé, “Ẹ ti tú àwọn aguntan mi ká, ẹ ti lé wọn dànù, ẹ kò sì tọ́jú wọn. N óo wá ṣe ìdájọ́ fun yín nítorí iṣẹ́ ibi yín, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ ní ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín níyà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni OLÚWA wí.