Jeremiah 23:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi, wọn ì bá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi. Wọn ì bá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ènìyàn wọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nà àti ìṣe búburú wọn.