Jeremiah 23:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.