Jeremiah 23:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni OLÚWA wí.