Jeremiah 23:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo kó àwọn tí wọ́n kù ninu àwọn aguntan mi jọ láti gbogbo ibi tí mo lé wọn lọ. N óo kó wọn pada sinu agbo wọn. Wọn óo bímọ lémọ, wọn óo sì máa pọ̀ sí i.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èmi OLÚWA tìkálárami yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀ èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí síi, tí wọn ó sì pọ̀ síi.