Jeremiah 23:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòótọ́, mo lòdì sí àwọn tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àlá èké,” ni OLÚWA wí. “Wọ́n ń sọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń mú àwọn ènìyàn mi sìnà nípa onírúurú èké wọn, síbẹ̀ èmi kò rán wọn tàbí yàn wọ́n. Wọn kò sì ran àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ bí ó ti wù kí ó kéré mọ,” ni OLÚWA wí.