Jeremiah 23:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ OLÚWA’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run alágbára alààyè padà.