Jeremiah 23:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè, n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, sa wò o, Emi o gbagbe nyin patapata, emi o si kọ̀ nyin silẹ, emi o si tì nyin jade, ati ilu ti mo fi fun nyin ati fun awọn baba nyin, kuro niwaju mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, Èmi yóò gbàgbé yín, bẹ́ẹ̀ ni n ó lé e yín kúrò níwájú mi pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè tí mo fi fún un yín àti àwọn baba yín.