Jeremiah 23:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Wò ó! Àkókò kan ń bọ̀, tí n óo gbé Ẹ̀ka olódodo kan dìde ninu ìdílé Dafidi. Yóo jọba, yóo hùwà ọlọ́gbọ́n, yóo sì ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo ní ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni OLÚWA wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dáfídì, Ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.