Jeremiah 23:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn tí wọn yóo máa wí pé, ‘Ní orúkọ OLUWA tí ó kó àwọn ọmọ ilé Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá, ati gbogbo ilẹ̀ tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ, tí ó sì mú wọn pada sí ilẹ̀ wọn.’ Wọn óo wá máa gbé orí ilẹ̀ wọn nígbà náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọn yóò máa wí pé, ‘Dájúdájú OLÚWA ń bẹ tí ó mú irú ọmọ ilé Ísírẹ́lì wá láti ilẹ̀ àríwá àti láti àwọn ilẹ̀ ibi tí mo tí lé wọn lọ,’ wọn ó sì gbé inú ilẹ̀ wọn.”