Jeremiah 23:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọkàn mi bàjẹ́ nítorí àwọn wolii, gbogbo ara mi ń gbọ̀n. Mo dàbí ọ̀mùtí tí ó ti mu ọtí yó, mo dàbí ẹni tí ọtí ń pa, nítorí OLUWA, ati nítorí ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si awọn woli. Ọkàn mi ti bajẹ ninu mi, gbogbo egungun mi mì; emi dabi ọmuti, ati ọkunrin ti ọti-waini ti bori rẹ̀ niwaju Oluwa, ati niwaju ọ̀rọ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ti àwọn wòlíì èké: Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi, gbogbo egungun mi ni ó wárìrì. Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn, bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa; nítorí OLÚWA àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.