Jeremiah 24:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ti kó Jékóníà ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà àti àwọn ìjòyè wọn, àwọn oníṣọ̀nà àti oníṣẹ́ ọwọ́ ti Júdà lọ sí ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mù lọ sí ilẹ̀ àjòjì Bábílónì tán. OLÚWA fi agbọ̀n èṣo ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí tí a gbé sí iwájú pẹpẹ OLÚWA.