Jeremiah 24:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?” Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA bi mí pé, “Kí ni ìwọ rí Jeremáyà?” “Èṣo ọ̀pọ̀tọ́” Mo dáhùn. “Èyí tí ó dára dára púpọ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó burú burú rékọjá tí kò sì ṣe é jẹ.”