Jeremiah 24:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí á kó lẹ́rú láti ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, ni pé, n óo kà wọ́n sí rere gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọnyi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí àwọn èṣo ọ̀pọ̀tọ́ dáradára yìí ni Èmi yóò ka àwọn tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ àjòjì láti Júdà sí tí èmi rán jáde kúrò ní ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará kálídéà