Jeremiah 24:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ohun tí OLUWA sọ nípa Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n kù ní ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ni pé òun óo ṣe wọ́n bí èso burúkú tí kò ṣe é jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ biburujù ti a kò le jẹ, nitoriti nwọn burujù, bayi li Oluwa wi, Bẹ̃ gẹgẹ ni emi o ṣe Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn ti o kù ni Jerusalemu, ati awọn iyokù ni ilẹ yi ati awọn ti ngbe ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni OLÚWA wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Ṣedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jérúsálẹ́mù, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Éjíbítì.