Jeremiah 25:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremáyà wá nípa àwọn ènìyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jéhóíákímù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadinésárì Ọba Bábílónì.