Jeremiah 25:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí aadọrin ọdún bá pé, n óo jẹ ọba Babiloni ati orílẹ̀-èdè rẹ̀, ati ilẹ̀ àwọn ará Kalidea níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo sì sọ ibẹ̀ di àlàpà títí ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ Ọba Bábílónì àti orílẹ̀ èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni OLÚWA wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé.