Jeremiah 25:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo mú gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú tí mo ti sọ nípa ilẹ̀ náà ṣẹ, ati gbogbo ohun tí a kọ sinu ìwé yìí, àní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jeremaya sọ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ ani gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè.