Jeremiah 25:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jérúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà, àwọn Ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.