Jeremiah 25:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn enia ajeji, ati gbogbo ọba ilẹ Usi, gbogbo ọba ilẹ Filistia, ati Aṣkeloni, ati Gasa, ati Ekroni, ati awọn iyokù Aṣdodi,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjòjì tí ó wà níbẹ̀; gbogbo àwọn Ọba Húsì, gbogbo àwọn Ọba Fílístínì, gbogbo àwọn ti Áṣíkélónì, Gásà, Ékírónì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Áṣídódì.