Jeremiah 25:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo awọn ọba ariwa, ti itosi ati ti ọ̀na jijin, ẹnikini pẹlu ẹnikeji rẹ̀, ati gbogbo ijọba aiye, ti mbẹ li oju aiye, ọba Ṣeṣaki yio si mu lẹhin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti gbogbo àwọn Ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jínjìn, ẹnìkìn-ín-ní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé. Àti gbogbo wọn, Ọba Ṣéṣákì náà yóò sì mu.