Jeremiah 25:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ mu, ki ẹ si mu amuyo, ki ẹ bì, ki ẹ si ṣubu, ki ẹ má si le dide mọ́, nitori idà ti emi o rán sãrin nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà, sọ fún wọn: Èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Mu, kí o sì mu amuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárin yín.