Jeremiah 25:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sa wò o, nitori ti emi bẹrẹ si imu ibi wá sori ilu na ti a pè li orukọ mi, ẹnyin fẹ ijẹ alaijiya? ẹnyin kì yio ṣe alaijiya: nitori emi o pè fun idà sori gbogbo olugbe aiye, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀ èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò há a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sọ.’