Jeremiah 25:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ní, “Fún ọdún mẹtalelogun, láti ọdún kẹtala tí Josaya ọmọ Amoni ti jọba Juda, títí di ọjọ́ òní, ni OLUWA ti ń bá mi sọ̀rọ̀, tí mo sì ti ń sọ ọ́ fun yín lemọ́lemọ́, ṣugbọn tí ẹ kò sì gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún odidi ọdún mẹ́talélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Jòsáyà, ọmọ Ámónì Ọba Júdà, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, àmọ́ ẹ̀yin kò fetí sílẹ̀.