Jeremiah 25:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé: ‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè, yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀. Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀. Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ iwọ sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Oluwa yio kọ lati oke wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ lati ibugbe rẹ̀ mimọ́, ni kikọ, yio kọ sori ibugbe rẹ̀, yio pariwo sori gbogbo olugbe aiye, bi awọn ti ntẹ ifunti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsinyìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn: “ ‘Kí o sì sọ pé, OLÚWA yóò bú láti òkè wá, yóò sì bú àrá kíkankíkan sí ilẹ̀ náà. Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí