Jeremiah 25:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ariwo náà yóo kàn dé òpin ayé, nítorí pé OLUWA ní ẹjọ́ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè rò. Yóo dá gbogbo eniyan lẹ́jọ́, yóo fi idà pa àwọn eniyan burúkú, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Igbe kan yio wá titi de opin ilẹ aiye; nitori Oluwa ni ijà ti yio ba awọn orilẹ-ède ja, yio ba gbogbo ẹran-ara wijọ, yio fi awọn oluṣe-buburu fun idà, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé, nítorí pé OLÚWA yóò mú ìjà wá sí orí àwọn orílẹ̀ èdè náà, yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn, yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ” ni OLÚWA wí.