Jeremiah 25:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òkú àwọn tí OLUWA yóo pa ní ọjọ́ náà yóo kún inú ayé láti òpin kan dé ekeji. Ẹnikẹ́ni kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, kò sí ẹni tí yóo gbé òkú wọn nílẹ̀; wọn kò ní sin wọ́n. Wọn yóo dàbí ìgbẹ́ lórí ilẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti Oluwa pa yio wà li ọjọ na lati ipẹkun kini aiye titi de ipẹkun keji aiye, a kì yio ṣọ̀fọ wọn, a kì yio ko wọn jọpọ, bẹ̃ni a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan lori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, àwọn tí OLÚWA ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò sọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.