Jeremiah 25:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ke! ẹnyin oluṣọ-agutan! ki ẹ si sọkun! ẹ fi ara nyin yilẹ ninu ẽru, ẹnyin ọlọla agbo-ẹran! nitori ọjọ a ti pa nyin ati lati tú nyin ka pe, ẹnyin o si ṣubu bi ohun-elo iyebiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùsọ́ àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran, nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.