Jeremiah 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ ati iṣẹ́ ibi tí ó ń ṣe, kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí OLUWA fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín títí lae, láti ìgbà àtijọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé.