Jeremiah 25:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ní kí ẹ má wá àwọn oriṣa lọ, kí ẹ má bọ wọ́n, kí ẹ má sì sìn wọ́n. Wọ́n ní kí ẹ má fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú un bínú, kí ó má baà ṣe yín ní ibi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe tọ àwọn Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”