Jeremiah 26:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ tún ọ̀nà yín ṣe, ẹ pa ìṣe yín dà, kí ẹ sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, yóo sì yí ọkàn rẹ̀ pada kúrò ninu ibi tí ó sọ pé òun yóo ṣe sí i yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, ẹ tun ọ̀na nyin ati iṣe nyin ṣe, ki ẹ si gbọ́ ohùn Oluwa Ọlọrun nyin; Oluwa yio si yi ọkàn rẹ̀ pada niti ibi ti o sọ si nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìnyìí, tún ọ̀nà rẹ ṣe àti ìṣe rẹ, kí ẹ sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run yín. OLÚWA yóò yí ọkàn rẹ̀ padà, kò sì ní mú ohun gbogbo tí ó ti sọ jáde ní búburú ṣẹ lórí yín.