Jeremiah 26:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé bí ẹ bá pa mí, ẹ óo fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sórí ara yín, ati ìlú yìí ati àwọn ará ìlú yìí, nítorí pé nítòótọ́ ni OLUWA rán mi pé kí n sọ gbogbo ohun tí mo sọ kí ẹ gbọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sibẹ, ẹ mọ̀ eyi daju pe, bi ẹ ba pa mi, mimu ni ẹnyin o mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ wá sori nyin ati sori ilu yi, ati sori awọn olugbe rẹ̀: nitori li otitọ Oluwa li o rán mi si nyin lati sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi li eti nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni OLÚWA ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”