Jeremiah 26:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan bá sọ fún àwọn alufaa ati àwọn wolii pé, “Ẹjọ́ ikú kò tọ́ sí ọkunrin yìí, nítorí pé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa ni ó fi ń bá wa sọ̀rọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn ijoye ati gbogbo enia sọ fun awọn alufa ati awọn woli pe, ọkunrin yi kò yẹ lati kú; nitoriti o sọ̀rọ fun wa li orukọ Oluwa, Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn aláṣẹ àti gbogbo àwọn ènìyàn sọ fún àwọn àlùfáà àti àwọn wòlíì pé, “Ẹ má ṣe pa ọkùnrin yìí nítorí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ ní orúkọ OLÚWA àwọn ọmọ ogun.”