Jeremiah 26:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko, Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà; òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mikah, ara Moraṣi, ṣe woli li ọjọ Hesekiah, ọba Juda, o si wi fun gbogbo enia Juda pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalemu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Míkà ti Mórásì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Heṣekáyà Ọba Júdà. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Júdà pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: “ ‘A ó sì fa Síónì tu bí oko Jérúsálẹ́mù yóò di òkítì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’