Jeremiah 26:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ Hesekaya ati gbogbo eniyan Juda pa Mika bí? Ṣebí OLUWA yí ibi tí ó ti pinnu láti ṣe sí wọn pada, nítorí pé Hesekaya bẹ̀rù OLUWA ó sì wá ojurere rẹ̀. Ṣugbọn ní tiwa ibi ńláńlá ni a fẹ́ fà lé orí ara wa yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ, Hesekiah, ọba Juda, ati gbogbo Juda ha pa a bi? Ẹ̀ru Oluwa kò ha bà a, kò ha bẹ Oluwa bi? Oluwa si yi ọkàn pada niti ibi ti o ti sọ si wọn; Bayi li awa iba ṣe mu ibi nla wá sori ẹmi wa?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ Heṣekáyà Ọba Júdà tàbí ẹnikẹ́ni ní Júdà pa á bí? Ǹjẹ́ Heṣekáyà kò bẹ̀rù OLÚWA tí ó sì wá ojúrere rẹ̀? Ǹjẹ́ OLÚWA kò há a sì yí ìpinnu rẹ̀ padà, tí kò sì mú ibi tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ kúrò lórí wọn? Ibi ni a fẹ́ mú wá sórí ara wa yìí.”