Jeremiah 26:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, Duro ni àgbala ile Oluwa, ki o si sọ fun gbogbo ilu Juda ti o wá lati sìn ni ile Oluwa gbogbo ọ̀rọ ti mo pa laṣẹ fun ọ lati sọ fun wọn: máṣe ke ọ̀rọ kanṣoṣo kù:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: Dúró ní àgbàlà ilé OLÚWA, kí o sì sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ Júdà tí ó ti wá láti wá jọ́sìn ní ilé OLÚWA: sọ gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún ọ; má ṣaláìsọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà.