Jeremiah 26:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin kan tún wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uraya, ọmọ Ṣemaaya, láti ìlú Kiriati Jearimu. Òun náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ yìí ati ilẹ̀ wa bí Jeremaya ti sọ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan si wà ẹ̀wẹ, ti o sọ asọtẹlẹ ni orukọ Oluwa, ani Urijah, ọmọ Ṣemaiah, ara Kirjatjearimu, ti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, ati si ilẹ yi, gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ Jeremiah.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Bákan náà Úráyà ọmọ Ṣémáíà láti Kúríátì Jéárímù jẹ́ ọkùnrin mìíràn tí ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà ní orúkọ OLÚWA. Ó sọ àṣọtẹ́lẹ̀ kan náà sí ìlú náà àti ilẹ̀ yín bí Jeremáyà ti ṣe.