Jeremiah 26:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nigbati Jehoiakimu, ọba, pẹlu gbogbo ọkunrin alagbara rẹ̀, ati awọn ijoye gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ọba nwá a lati pa; ṣugbọn nigbati Urijah gbọ́, o bẹ̀ru, o salọ o si wá si Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ọba Jéhóíákímù àti gbogbo àwọn aláṣẹ gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba ń wá láti pa á: ṣùgbọ́n Úráyà gbọ́ èyí, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí Éjíbítì.