Jeremiah 26:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mà á jẹ́ kí ilé yìí dàbí sílò, n ó sọ ìlú yìí kí ó dàbí ìfibú fún gbogbo àgbáyé.’ ”