Jeremiah 26:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati Jeremiah pari gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa paṣẹ fun u lati sọ fun gbogbo enia, nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia di i mu wipe, kikú ni iwọ o kú!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní kété tí Jeremáyà ti parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí OLÚWA pa láṣẹ láti sọ; àwọn àlùfáà, àti gbogbo ènìyàn dì í mú, wọ́n sì wí pé, “Kíkú ni ìwọ yóò kú!