Jeremiah 26:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ló dé tí ìwọ ṣe sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLÚWA pé, ilé yìí yóò dàbí ṣílò, orílẹ̀ èdè yìí yóò sì di ahoro tí kì yóò ní olùgbé.” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kójọpọ̀ pẹ̀lú Jeremáyà nínú ilé OLÚWA.