Jeremiah 27:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn orilẹ-ède na ti o mu ọrùn rẹ̀ wá si abẹ àjaga ọba Babeli, ti o si sìn i, on li emi o jẹ ki o joko ni ilẹ wọn, li Oluwa wi, yio si ro o, yio si gbe ibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀ èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà Ọba Bábílónì, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni OLÚWA wí.” ’ ”