Jeremiah 27:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii tí wọn ń wí fun yín pé ẹ kò ní ṣe ẹrú ọba Babiloni, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ má ṣe fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin Ọba Bábílónì,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ eké ni wọ́n ń sọ fún un yín.