Jeremiah 27:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní òun kò rán wọn níṣẹ́. Wọ́n kàn ń fi orúkọ òun sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni, kí òun lè le yín jáde, kí ẹ sì ṣègbé, àtẹ̀yin àtàwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èmi kò rán wọn ni OLÚWA wí. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Nítorí náà, Èmi yóò lé wọn, wọn yóò sì ṣègbé, ẹ̀yin pẹ̀lú àwọn wòlíì tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún un yín.’ ”