Jeremiah 27:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn bá jẹ́ wolii nítòótọ́, bí ó bá jẹ́ pé èmi OLUWA ni mo fi ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu, ẹ ní kí wọn gbadura sí èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun, kí n má jẹ́ kí wọ́n kó àwọn ohun èlò tí ó kù ní ilé OLUWA ati ní ààfin ọba Juda ati ní Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ OLÚWA, jẹ́ kí wọ́n bẹ OLÚWA kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Júdà àti Jérúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.