Jeremiah 27:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
wọn óo kó lọ sí Babiloni, níbẹ̀ ni wọn yóo sì wà títí di ọjọ́ tí mo bá ranti wọn. N óo wá kó wọn pada wá sí ibí yìí nígbà náà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A o kó wọn lọ si Babeli, nibẹ ni nwọn o wà titi di ọjọ na ti emi o bẹ̀ wọn wò, li Oluwa wi, emi o si mu wọn goke wá, emi o si mu wọn pada wá si ibi yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Bábílónì, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ OLÚWA. ‘Lẹ́yìn èyí, mà á mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”